Mark 15:2-5

2 aPilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”

Jesu sì dáhùn pé, “gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.”

3Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án. 4Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”

5Ṣùgbọ́n Jesu kò dalóhùn síbẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pilatu.

Copyright information for YorBMYO